Oríkì Buhari (apá kínní)

Oríkì Buhari (apá kínní)

Intigrity tí kò lẹ́gbẹ́
Ẹkùn ọkọ ”corruption”
Akatakítí, akìtìkata
O gbórí Ọbásanjọ́ ṣe ‘dájọ́ Àtíkù
Tó bá jẹ ti ká ṣe òdodo
Ọkọ ”Aishatu” Ajikẹ ni
”The last man standing” nínú olóṣèlú

Wọ́n nà án, ó sunkún
Ṣùgbọ́n ojú ẹ ò ṣ’omi
Òun wa nà wọ́n
Wọ́n wá ń t’omi lójú bíi t’egbére
Ògbólóògbó sọ́jà
Tí ń f’agbádá ṣè̀ ‘jọba

Wọ́n bú u, bú u
Etí rẹ fẹ́ẹ̀ di
Atúwọnká níbi wọ́n tí ń dáná irọ́
Àfìgbà tó́ dókè òkun
N letíi jagun to kọ̀rẹ́ẹ̀kìtì padà

Wọ́n pa á, pa á, kò kú
Ẹni t’Ọlọ́hun O pa
Igba Obi o le è firọ́ rán ní sàárè
Bi Buhari ò kú
Obituari Jubrin náà lẹ̀ ó máa lẹ̀ kiri

Buhari o
Ṣé kí n kúkú kì ọ lọ ‘lé àwọn bàbá rẹ?

#GBAM!

Ẹ ”watch out” fun ”part 2”
Ẹ kú ojú lọ́nà

#AKẸ́KỌ̀Ọ_1440

©Akewi Agbaye Akekoo Akoka.

3 thoughts on “Oríkì Buhari (apá kínní)

  1. Thank you for using this work on your blog. I will appreciate it more if you could add the copyright to it. As many people now copy and paste without the copyright attached to it. It carries my copyright ©Akewi Agbaye Akekoo Akoka.
    Thanks

    1. Sorry. I didnt know but I copied it from a source where your copyright wasnt acknowledged. Now i will appropriately edit to reflect your copyright ownership

Leave a Reply

Fill in your details below or click an icon to log in:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Google photo

You are commenting using your Google account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

Connecting to %s